Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́:níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko?Níbo ni wọ́n ti ń sinmi,nígbà tí oòrùn bá mú?Kí n má baà máa wá ọ kiri,láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ?