1. Àwọn orin tí ó dùn jùlọ tí Solomoni kọ nìwọ̀nyí:
2. Wá fi ẹnu kò mí lẹ́nu,nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí waini lọ.
3. Òróró ìpara rẹ ní òórùn dídùn,orúkọ rẹ dàbí òróró ìkunra tí a tú jáde;nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin ṣe fẹ́ràn rẹ.
4. Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá,ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀.Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹa óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ;abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ!