1. OLUWA jọba; ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí ẹ̀wù;OLUWA gbé ọlá ńlá wọ̀,ó sì di agbára ni àmùrè.Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;kò sì ní yẹ̀ laelae.
2. A ti fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ láti ìgbà laelae;láti ayérayé ni o ti wà.
3. Ibú omi gbé ohùn wọn sókè, OLUWA,ibú omi gbé ohùn wọn sókè,ó sì ń sán bí ààrá.