Orin Dafidi 92:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ṣugbọn ẹni àgbéga títí lae ni ọ́, OLUWA.

9. Wò ó, OLUWA, àwọn ọ̀tá rẹ yóo parun;gbogbo àwọn aṣebi yóo sì fọ́n ká.

10. Ṣugbọn o ti gbé mi ga, o ti fún mi lágbára bíi ti ẹfọ̀n;o ti da òróró dáradára sí mi lórí.

11. Mo ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi,mo sì ti fi etí mi gbọ́ ìparun àwọn ẹni ibi tí ó gbé ìjà kò mí.

12. Àwọn olódodo yóo gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹ,wọn óo dàgbà bí igi kedari ti Lẹbanoni.

13. Wọ́n dàbí igi tí a gbìn sí ilé OLUWA,tí ó sì ń dàgbà ninu àgbàlá Ọlọrun wa.

Orin Dafidi 92