Orin Dafidi 9:9-11 BIBELI MIMỌ (BM)

9. OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú.

10. Àwọn tí ó mọ̀ ọ́ yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ;nítorí ìwọ, OLUWA, kìí kọ àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀.

11. Ẹ kọrin ìyìn sí OLUWA, tí ó gúnwà ní Sioni!Ẹ kéde iṣẹ́ rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè!

Orin Dafidi 9