Orin Dafidi 85:9-13 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Nítòótọ́, ìgbàlà rẹ̀ wà nítòsí fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;kí ògo rẹ̀ lè wà ní ilẹ̀ wa.

10. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ yóo pàdé;òdodo ati alaafia yóo dì mọ́ ara wọn.

11. Òtítọ́ yóo rú jáde láti inú ilẹ̀;òdodo yóo sì bojú wolẹ̀ láti ojú ọ̀run.

12. Dájúdájú, OLUWA yóo fúnni ní ohun tí ó dára;ilẹ̀ wa yóo sì mú èso jáde lọpọlọpọ.

13. Òdodo yóo máa rìn lọ níwájú rẹ̀,yóo sì sọ ipasẹ̀ rẹ̀ di ọ̀nà.

Orin Dafidi 85