1. OLUWA, o fi ojurere wo ilẹ̀ rẹ;o dá ire Jakọbu pada.
2. O dárí àìdára àwọn eniyan rẹ jì wọ́n;o sì bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
3. O mú ìrúnú rẹ kúrò;o dáwọ́ ibinu gbígbóná rẹ dúró.
4. Tún mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun Olùgbàlà wa;dáwọ́ inú tí ń bí ọ sí wa dúró.
5. Ṣé o óo máa bínú sí wa títí lae ni?Ṣé ibinu rẹ yóo máa tẹ̀síwájú láti ìran dé ìran ni?
6. Ṣé o ò ní tún sọ wá jí ni,kí àwọn eniyan rẹ lè máa yọ̀ ninu rẹ?