7. àwọn ará Gebali, àwọn ọmọ Amoni, ati àwọn ọmọ Amaleki,àwọn ará Filistia ati àwọn tí ń gbé Tire.
8. Àwọn ará Asiria pàápàá ti dara pọ̀ mọ́ wọn;àwọn ni alátìlẹ́yìn àwọn ọmọ Lọti.
9. Ṣe wọ́n bí o ti ṣe àwọn ará Midiani,bí o ti ṣe Sisera ati Jabini ni odò Kiṣoni,
10. àwọn tí o parun ní Endori,tí wọ́n di ààtàn lórí ilẹ̀.
11. Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí o ti ṣe Orebu ati Seebu;ṣe àwọn ìjòyè wọn bí o ti ṣe Seba ati Salumuna,
12. àwọn tí ó wí pé,“Ẹ jẹ́ kí á mú lára ilẹ̀ Ọlọrunkí á sọ ọ́ di tiwa.”
13. Ọlọrun mi, ṣe wọ́n bí ààjà tíí ṣe ewé,àní, bí afẹ́fẹ́ tíí ṣe fùlùfúlù.
14. Bí iná tíí jó igbó,àní, bí ọwọ́ iná sì ṣe ń jó òkè kanlẹ̀,
15. bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì rẹ lé wọn,kí o sì fi ààjà rẹ dẹ́rù bà wọ́n.
16. Da ìtìjú bò wọ́n,kí wọn lè máa wá ọ kiri, OLUWA.
17. Jẹ́ kí ojú tì wọ́n, kí ìdààmú dé bá wọn títí lae,kí wọn sì ṣègbé ninu ìtìjú.
18. Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ nìkan,tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA,ni Ọ̀gá Ògo lórí gbogbo ayé.