Orin Dafidi 82:5-8 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Wọn kò ní ìmọ̀ tabi òye,wọ́n ń rìn kiri ninu òkùnkùn,títí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé fi mì tìtì.

6. Mo ní, “oriṣa ni yín,gbogbo yín ni ọmọ Ọ̀gá Ògo.

7. Ṣugbọn sibẹsibẹ, ẹ óo kú bí eniyan,ẹ ó sùn bí èyíkéyìí ninu àwọn ìjòyè.”

8. Dìde, Ọlọrun, ṣe ìdájọ́ ayé,nítorí tìrẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè!

Orin Dafidi 82