Orin Dafidi 81:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ kọ orin sókè sí Ọlọrun, agbára wa;ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun Jakọbu.

2. Ẹ dárin, ẹ lu samba, ẹ ta hapu dídùn ati lire.

3. Ẹ fọn fèrè ní ọjọ́ oṣù titun, ati níọjọ́ oṣù tí a yà sọ́tọ̀, ati ní ọjọ́ àsè.

4. Nítorí pé àṣẹ ni, fún àwọn ọmọ Israẹli,ìlànà sì ni, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Jakọbu.

Orin Dafidi 81