4. Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀?Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀?
5. O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ sí ti ìwọ Ọlọrun,o sì ti fi ògo ati ọlá dé e ní adé.
6. O mú un jọba lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,o sì fi gbogbo nǹkan sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
7. àwọn aguntan, ati àwọn mààlúù, ati gbogbo ẹranko ninu igbó;
8. àwọn ẹyẹ ojú ọrun, àwọn ẹja inú òkun,ati gbogbo nǹkan tí ó ń lúwẹ̀ẹ́ ninu òkun.
9. OLUWA, Oluwa wa,orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé!