3. Nígbà tí mo ṣe akiyesi ojú ọ̀run, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, tí o sọlọ́jọ̀–
4. Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀?Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀?
5. O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ sí ti ìwọ Ọlọrun,o sì ti fi ògo ati ọlá dé e ní adé.
6. O mú un jọba lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,o sì fi gbogbo nǹkan sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
7. àwọn aguntan, ati àwọn mààlúù, ati gbogbo ẹranko ninu igbó;