3. Mo ronú nípa Ọlọrun títí, mò ń kérora;mo ṣe àṣàrò títí, ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì.
4. OLUWA, o ò jẹ́ kí n dijú wò ní gbogbo òrumo dààmú tóbẹ́ẹ̀ tí n kò le sọ̀rọ̀.
5. Mo ranti ìgbà àtijọ́,mo ranti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.
6. Mo ronú jinlẹ̀ lóru,mo ṣe àṣàrò, mo yẹ ọkàn mi wò.
7. Ṣé Ọlọrun yóo kọ̀ wá sílẹ̀ títí lae ni;àbí inú rẹ̀ kò tún ní dùn sí wa mọ́?
8. Ṣé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ti pin títí lae ni;àbí ìlérí rẹ̀ ti dópin patapata?
9. Ṣé Ọlọrun ti gbàgbé láti máa ṣoore ni;àbí ó ti fi ibinu pa ojú àánú rẹ̀ dé?
10. Nígbà náà ni mo wí pé, “Ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́ ni péỌ̀gá Ògo kò jẹ́wọ́ agbára mọ́.”
11. N óo ranti àwọn iṣẹ́ OLUWA,àní, n óo ranti àwọn iṣẹ́ ìyanu ìgbàanì.
12. N óo máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ;n óo sì máa ronú lórí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.