Orin Dafidi 77:12-14 BIBELI MIMỌ (BM)

12. N óo máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ;n óo sì máa ronú lórí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe.

13. Ọlọrun, mímọ́ ni ọ̀nà rẹ;oriṣa wo ni ó tó Ọlọrun wa?

14. Ìwọ ni Ọlọrun tí ń ṣe ohun ìyanu;o ti fi agbára rẹ hàn láàrin àwọn eniyan.

Orin Dafidi 77