1. Àwọn ará Juda mọ Ọlọrun,orúkọ rẹ̀ sì lọ́wọ̀ ní Israẹli.
2. Ilé rẹ̀ wà ní Salẹmu,ibùgbé rẹ̀ wà ní Sioni.
3. Níbẹ̀ ni ó ti ṣẹ́ ọfà ọ̀tá tí ń rọ̀jò,ati apata, ati idà, ati àwọn ohun ìjà ogun.
4. Ológo ni ọ́, ọlá rẹ sì pọ̀,ó ju ti àwọn òkè tí ó kún fún ẹran lọ.