Orin Dafidi 67:3-7 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun;jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́!

4. Kí inú àwọn orílẹ̀-èdè ó dùn,kí wọn ó máa kọrin ayọ̀,nítorí pé ò ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan láìṣe ojuṣaaju;o sì ń tọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé.

5. Jẹ́ kí àwọn eniyan ó máa yìn ọ́, Ọlọrun;jẹ́ kí gbogbo eniyan máa yìn ọ́!

6. Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀ ìkórè jáde;Ọlọrun, àní Ọlọrun wa, bukun wa.

7. Ọlọrun bukun wa,kí gbogbo ayé máa bẹ̀rù rẹ̀.

Orin Dafidi 67