Orin Dafidi 65:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọrun, ìwọ ni ìyìn yẹ ní Sioni,ìwọ ni a óo san ẹ̀jẹ́ wa fún,

2. ìwọ tí ń gbọ́ adura!Ọ̀dọ̀ rẹ ni gbogbo eniyan ń bọ̀,

3. nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá borí wa,ìwọ a máa dáríjì wá.

4. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí o yàn,tí o mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,láti máa gbé inú àgbàlá rẹ.Àwọn ire inú ilé rẹ yóo tẹ́ wa lọ́rùn,àní, àwọn ire inú tẹmpili mímọ́ rẹ!

Orin Dafidi 65