1. Tẹ́tí sí adura mi, Ọlọrun,má sì fara pamọ́ nígbà tí mo bá ń bẹ̀bẹ̀.
2. Fetí sí mi, kí o sì dá mi lóhùn;ìṣòro ti borí mi.
3. Ìhàlẹ̀ ọ̀tá bà mí ninu jẹ́,nítorí ìnilára àwọn eniyan burúkú;wọ́n kó ìyọnu bá mi,wọ́n ń bínú mi, inú wọn sì dùn láti máa bá mi ṣọ̀tá.
4. Ọkàn mi wà ninu ìrora,ìpayà ikú ti dé bá mi.
5. Ẹ̀rù ati ìwárìrì dà bò mí,ìpayà sì bò mí mọ́lẹ̀.
6. Mo ní, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!Ǹ bá fò lọ, ǹ bá lọ sinmi.