Orin Dafidi 51:6-9 BIBELI MIMỌ (BM)

6. O fẹ́ràn òtítọ́ inú;nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi.

7. Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́;wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ.

8. Fún mi ní ayọ̀ ati inú dídùn,kí gbogbo egungun mi tí ó ti rún lè máa yọ̀.

9. Mójú kúrò lára ẹ̀ṣẹ̀ mi,kí o sì pa gbogbo àìdára mi rẹ́.

Orin Dafidi 51