1. Ẹ gbọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè!Ẹ dẹtí sílẹ̀, gbogbo aráyé,
2. ati mẹ̀kúnnù àtọlọ́lá,àtolówó ati talaka!
3. Ẹnu mi yóo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n;àṣàrò ọkàn mi yóo sì jẹ́ ti òye.
4. N óo tẹ́tí sílẹ̀ sí òwe;n óo sì fi hapu túmọ̀ rẹ̀.
5. Kí ló dé tí n óo fi bẹ̀rù ní àkókò ìyọnu,nígbà tí iṣẹ́ ibi àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi bá yí mi ká,
6. àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,tí wọ́n sì ń yangàn nítorí wọ́n ní ọrọ̀ pupọ?