1. Ọlọrun ni ààbò ati agbára wa,olùrànlọ́wọ́ tí ó wà nítòsí nígbà gbogbo, ní ìgbà ìpọ́njú.
2. Nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà wá bí ayé tilẹ̀ ṣídìí,bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣípò pada, tí wọ́n bọ́ sinu òkun;
3. bí omi òkun tilẹ̀ ń hó, tí ó sì ń ru,tí àwọn òkè ńlá sì ń mì tìtìnítorí agbára ríru rẹ̀.
4. Odò kan wà tí omi rẹ̀ ń mú inú ìlú Ọlọrun dùn,ìlú yìí ni ibùgbé mímọ́ Ọ̀gá Ògo.
5. Ọlọrun wà láàrin rẹ̀,kò ní tú bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣí kúrò;Ọlọrun yóo ràn án lọ́wọ́ ní òwúrọ̀ kutukutu.