11. Nígbà tí o bá jẹ eniyan níyàpẹlu ìbáwí nítorí ẹ̀ṣẹ̀,ìwọ á ba ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún un jẹ́ bíi kòkòrò aṣọ.Dájúdájú, afẹ́fẹ́ lásán ni eniyan.
12. “OLUWA, gbọ́ adura mi,tẹ́tí sí igbe mi,má dágunlá sí ẹkún mi,nítorí pé àlejò rẹ, tí ń rékọjá lọ ni mo jẹ́;àjèjì sì ni mí, bíi gbogbo àwọn baba mi.
13. Mú ojú ìbáwí kúrò lára mi,kí inú mi lè dùn kí n tó kọjá lọ;àní, kí n tó ṣe aláìsí.”