17. Nítorí pé mo ti fẹ́rẹ̀ ṣubú,mo sì wà ninu ìrora nígbà gbogbo.
18. Mo jẹ́wọ́ àṣìṣe mi,mo sì káàánú fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
19. Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí lágbára,àwọn tí ó kórìíra mi láìtọ́ sì pọ̀.
20. Àwọn tí ń fi ibi san oore fún mi ní ń gbógun tì mí,nítorí pé rere ni mò ń ṣe.
21. OLUWA, má kọ̀ mí sílẹ̀,Ọlọrun mi, má jìnnà sí mi.
22. Yára wá ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, ìgbàlà mi.