Orin Dafidi 38:15-18 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ṣugbọn, OLUWA, ìwọ ni mò ń dúró dè;OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni o óo dá mi lóhùn.

16. Nítorí tí mò ń gbadura pé,kí àwọn tí ń pẹ̀gàn mi má yọ̀ mínígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yẹ̀.

17. Nítorí pé mo ti fẹ́rẹ̀ ṣubú,mo sì wà ninu ìrora nígbà gbogbo.

18. Mo jẹ́wọ́ àṣìṣe mi,mo sì káàánú fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.

Orin Dafidi 38