Orin Dafidi 37:35-40 BIBELI MIMỌ (BM)

35. Mo ti rí eniyan burúkú tí ń halẹ̀ mọ́ni,tí ó ga bí igi kedari ti Lẹbanoni.

36. Ṣugbọn nígbà tí mo tún gba ibẹ̀ kọjá,mo wò ó, kò sí níbẹ̀ mọ́;mo wá a, ṣugbọn n kò rí i.

37. Ṣe akiyesi ẹni pípé;sì wo olódodo dáradára,nítorí pé ìgbẹ̀yìn ẹni tí ń wá alaafia yóo dára.

38. Ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo parun patapata,a óo sì run ọmọ àwọn eniyan burúkú.

39. Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìgbàlà àwọn olódodo ti ń wá;òun ni alátìlẹ́yìn wọn ní àkókò ìṣòro.

40. OLUWA a máa ràn wọ́n lọ́wọ́, a sì máa gbà wọ́n;a máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,a sì máa gbà wọ́n là,nítorí pé òun ni wọ́n sá di.

Orin Dafidi 37