Orin Dafidi 34:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. N óo máa yin OLUWA ní gbogbo ìgbà;ìyìn rẹ̀ yóo máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo.

2. OLUWA ni èmi óo máa fi yangàn;kí inú àwọn olùpọ́njú máa dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́.

3. Ẹ bá mi gbé OLUWA ga,ẹ jẹ́ kí á jùmọ̀ gbé orúkọ rẹ̀ lékè!

Orin Dafidi 34