Orin Dafidi 22:15-18 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Okun inú mi ti gbẹ bí àpáàdì,ahọ́n mi sì ti lẹ̀ mọ́ mi lẹ́nu;o ti fi mí sílẹ̀ sinu eruku isà òkú.

16. Àwọn eniyan burúkú yí mi ká bí ajá;àwọn aṣebi dòòyì ká mi;wọ́n fa ọwọ́ ati ẹsẹ̀ mi ya.

17. Mo lè ka gbogbo egungun miwọ́n tẹjúmọ́ mi; wọ́n ń fojú burúkú wò mí.

18. Wọ́n pín aṣọ mi láàrin ara wọn,wọ́n ṣẹ́ gègé nítorí ẹ̀wù mi.

Orin Dafidi 22