1. OLUWA, ta ni ó lè máa gbé inú àgọ́ rẹ?Ta ni ó lè máa gbé orí òkè mímọ́ rẹ?
2. Ẹni tí ń rìn déédéé, tí ń ṣe òdodo;tí sì ń fi tọkàntọkàn sọ òtítọ́.
3. Ẹni tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ eniyan lẹ́yìn,tí kò ṣe ibi sí ẹnìkejì rẹ̀,tí kò sì sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nípa aládùúgbò rẹ̀.
4. Ẹni tí kò ka ẹni ẹ̀kọ̀ sí,ṣugbọn a máa bu ọlá fún àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA;bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́, kì í yẹ̀ ẹ́;bí ẹ̀jẹ́ tí ó ti wù kí ó nira tó.