Orin Dafidi 147:17-20 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ó sọ yìnyín sílẹ̀ bí òkò,ta ni ó lè fara da òtútù rẹ̀?

18. Ó sọ̀rọ̀, wọ́n yọ́,ó fẹ́ afẹ́fẹ́, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn.

19. Ó ṣí ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá fún Jakọbu,ó sì fi òfin ati ìlànà rẹ̀ han Israẹli.

20. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè kankan rí,wọn kò sì mọ ìlànà rẹ̀.Ẹ yin OLUWA!

Orin Dafidi 147