Orin Dafidi 141:6-10 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nígbà tí ọwọ́ àwọn tí yóo dá wọn lẹ́bi bá tẹ̀ wọ́n,wọn óo gbà pé, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA.

7. Bí òkúta tí eniyan là, tí ó fọ́ yángá-yángá sílẹ̀,ni a óo fọ́n egungun wọn ká sí ẹnu ibojì.

8. Ṣugbọn ìwọ ni mo gbójúlé, OLUWA, Ọlọrun.Ìwọ ni asà mi,má fi mí sílẹ̀ láìní ààbò.

9. Pa mí mọ́ ninu ewu tàkúté,ati ti okùn tí àwọn aṣebi dẹ sílẹ̀ dè mí.

10. Jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú ṣubú sinu àwọ̀n ara wọn,kí èmi sì lọ láìfarapa.

Orin Dafidi 141