Orin Dafidi 140:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi;dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá;

2. àwọn tí ó ń pète ibi lọ́kàn wọn,tí wọ́n sì ń dá ogun sílẹ̀ nígbàkúùgbà,

3. Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn, ó mú bí ahọ́n ejò;oró paramọ́lẹ̀ sì ń bẹ ninu eyín wọn.

Orin Dafidi 140