1. N óo máa yìn ọ́ tọkàntọkàn OLUWA,lójú àwọn oriṣa ni n óo máa kọrin ìyìn sí ọ.
2. Ní ìtẹríba, n óo kọjú sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ,n óo sì máa yin orúkọ rẹ,nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ,nítorí pé o gbé ọ̀rọ̀ rẹ ati orúkọ rẹ ga ju ohunkohun lọ.