Orin Dafidi 137:5-7 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Jerusalẹmu, bí mo bá gbàgbé rẹ,kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó rọ.

6. Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ èrìgì mi,bí n kò bá ranti rẹ,bí n kò bá sì fi Jerusalẹmu ṣe olórí ayọ̀ mi.

7. OLUWA, ranti ohun tí àwọn ará Edomu ṣenígbà tí Jerusalẹmu bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá,tí wọn ń pariwo pé,“Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀.”

Orin Dafidi 137