8. Ó dá oòrùn láti máa ṣe àkóso ọ̀sán,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
9. Ó dá òṣùpá ati ìràwọ̀ láti máa ṣe àkóso òru,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
10. Ẹni tí ó pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
11. ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láàrin wọn,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
12. Pẹlu ipá ati ọwọ́ líle ni ó fi kó wọn jáde,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
13. Ẹni tí ó pín Òkun Pupa sí meji,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;