10. Ẹni tí ó pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
11. ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láàrin wọn,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
12. Pẹlu ipá ati ọwọ́ líle ni ó fi kó wọn jáde,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
13. Ẹni tí ó pín Òkun Pupa sí meji,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
14. ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli kọjá láàrin rẹ̀,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
15. ṣugbọn ó bi Farao ati àwọn ọmọ ogunrẹ̀ ṣubú ninu Òkun Pupa,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
16. Ẹni tí ó mú àwọn eniyan rẹ̀ la aṣálẹ̀ já,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
17. ẹni tí ó pa àwọn ọba ńlá,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
18. ó sì pa àwọn ọba olókìkí,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
19. Sihoni ọba àwọn Amori,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
20. ati Ogu ọba Baṣani,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.