Orin Dafidi 135:19-21 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ yin OLUWA,ẹ̀yin ará ilé Aaroni, ẹ yin OLUWA!

20. Ẹ̀yin ará ilé Lefi, ẹ yin OLUWA,ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ yìn ín!

21. Ẹ yin OLUWA ní Sioni,ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu!Ẹ yin OLUWA!

Orin Dafidi 135