1. Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi.Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé,
2. “Ọpọlọpọ ìgbà ni wọ́n ti ń pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi,sibẹ, wọn kò borí mi.”
3. Wọ́n to ẹgba sí mi lẹ́yìn,gbogbo ẹ̀yìn mi lé bíi poro oko.
4. Ṣugbọn olódodo ni OLUWA,ó ti gé okùn àwọn eniyan burúkú.