2. “Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wanígbà tí ọmọ aráyé gbógun tì wá,
3. wọn ìbá gbé wa mì láàyè,nígbà tí inú bí wọn sí wa;
4. àgbàrá ìbá ti gbá wa lọ,ìṣàn omi ìbá ti bò wá mọ́lẹ̀;
5. ìgbì omi ìbá ti gbé wa mì.”
6. Ọpẹ́ ni fún OLUWA,tí kò fi wá ṣe ẹran ìjẹ fún wọn.
7. A ti yọ, bí ẹyẹ tí ó yọ ninu okùn apẹyẹ:okùn ti já; àwa sì ti yọ.
8. Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìrànlọ́wọ́ wa ti wá,ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé.