Orin Dafidi 122:5-9 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Níbẹ̀ ni a tẹ́ ìtẹ́ ìdájọ́ sí,àní, ìtẹ́ ìdájọ́ àwọn ọba ìdílé Dafidi.

6. Gbadura fún alaafia Jerusalẹmu!“Yóo dára fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ!

7. Kí alaafia ó wà ninu rẹ,kí ìbàlẹ̀ àyà wà ninu ilé ìṣọ́ rẹ.”

8. Nítorí ti àwọn ará ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi,n óo wí pé, “Kí alaafia ó wà ninu rẹ.”

9. Nítorí ti ilé OLUWA, Ọlọrun wa,èmi óo máa wá ire rẹ.

Orin Dafidi 122