1. Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé,“Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé OLUWA.”
2. A ti tẹsẹ̀ bọ inú ìgboro rẹ, Jerusalẹmu.
3. Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí a kọ́,tí gbogbo rẹ̀ já pọ̀ di ọ̀kan.
4. Níbi tí àwọn ẹ̀yà,àní, àwọn ẹ̀yà eniyan OLUWA máa ń gòkè lọ,láti dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWAgẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí a pa fún Israẹli.
5. Níbẹ̀ ni a tẹ́ ìtẹ́ ìdájọ́ sí,àní, ìtẹ́ ìdájọ́ àwọn ọba ìdílé Dafidi.
6. Gbadura fún alaafia Jerusalẹmu!“Yóo dára fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ!