Orin Dafidi 121:5-7 BIBELI MIMỌ (BM)

5. OLUWA ni olùpamọ́ rẹ.OLUWA yóo ṣíji bò ọ́ ní apá ọ̀tún rẹ.

6. Oòrùn kò ní ṣe ọ́ léṣe lọ́sàn-án,bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá kò ní pa ọ́ lára lóru.

7. OLUWA óo dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ gbogbo ibi,yóo pa ọ́ mọ́.

Orin Dafidi 121