Orin Dafidi 119:80-83 BIBELI MIMỌ (BM)

80. Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé,kí ojú má baà tì mí.

81. Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi;ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.

82. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ.Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?”

83. Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì,sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ.

Orin Dafidi 119