8. N óo máa pa òfin rẹ mọ́,má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata.
9. Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́?Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni.
10. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ,má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ.
11. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn,kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.
12. Ìyìn ni fún ọ, OLUWA,kọ́ mi ní ìlànà rẹ!
13. Mo fi ẹnu mi kéde gbogbo àṣẹ tí o pa.
14. Mo láyọ̀ ninu pípa òfin rẹ mọ́,bí ẹni tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.
15. N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ,n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ.
16. N óo láyọ̀ ninu àwọn ìlànà rẹ,n kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.
17. Ṣe ọpọlọpọ oore fún èmi iranṣẹ rẹ,kí n lè wà láàyè,kí n sì máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
18. Là mí lójú, kí n lè rí àwọn nǹkan ìyanutí ó wà ninu òfin rẹ.
19. Àlejò ni mí láyé,má fi òfin rẹ pamọ́ fún mi.
20. Òùngbẹ títẹ̀lé òfin rẹ ń gbẹ ọkàn mi, nígbà gbogbo.
21. O bá àwọn onigbeeraga wí, àwọn ẹni ègún,tí wọn kò pa òfin rẹ mọ́.