Orin Dafidi 119:66-72 BIBELI MIMỌ (BM)

66. Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé,nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ.

67. Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ;ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ.

68. OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe;kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

69. Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀,ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́.

70. Ọkàn wọn ti yigbì,ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ.

71. Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani,ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ.

72. Òfin rẹ níye lórí fún mi,ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ.

Orin Dafidi 119