Orin Dafidi 119:52-61 BIBELI MIMỌ (BM)

52. Mo ranti òfin rẹ àtijọ́,OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀.

53. Inú mi á máa ru,nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú,tí wọn ń rú òfin rẹ.

54. Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ,lákòókò ìrìn àjò mi láyé.

55. Mo ranti orúkọ rẹ lóru;OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́:

56. Èyí ni ìṣe mi:Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́.

57. OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní;mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́.

58. Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ,ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.

59. Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi,mo yipada sí ìlànà rẹ;

60. mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́.

61. Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi,n kò ní gbàgbé òfin rẹ.

Orin Dafidi 119