40. Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ,sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ!
41. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA,kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
42. Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn,nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43. Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá,nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ.
44. N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae.
45. N óo máa rìn fàlàlà,nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ.
46. N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba,ojú kò sì ní tì mí.
47. Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ,nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀.