34. Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́,kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́.
35. Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ,nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀.
36. Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ,kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé.
37. Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán,sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ.
38. Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ,àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ.
39. Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò,nítorí pé ìlànà rẹ dára.