Orin Dafidi 119:135-139 BIBELI MIMỌ (BM)

135. Jẹ́ kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ sí ara èmi iranṣẹ rẹ;kí o sì kọ́ mi ní ìlànà rẹ.

136. Omijé ń dà lójú mi pòròpòrò,nítorí pé àwọn eniyan kò pa òfin rẹ mọ́.

137. Olódodo ni ọ́, OLUWA,ìdájọ́ rẹ sì tọ́.

138. Òdodo ni o fi pa àṣẹ rẹ,òtítọ́ patapata ni.

139. Mò ń tara gidigidi,nítorí pé àwọn ọ̀tá mi gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.

Orin Dafidi 119