Orin Dafidi 115:5-13 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Wọ́n ní ẹnu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀,wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò ríran.

6. Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn,wọ́n nímú, ṣugbọn wọn kò gbóòórùn.

7. Wọ́n lọ́wọ́, ṣugbọn wọn kò lè lò ó,wọ́n lẹ́sẹ̀, ṣugbọn wọn kò lè rìn,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbin.

8. Àwọn tí ó ń yá àwọn ère náà dàbí wọn,bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé wọn.

9. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.

10. Ẹ̀yin ìdílé Aaroni, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.

11. Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ gbẹ́kẹ̀lé e,òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.

12. OLUWA ranti wa, yóo bukun wa,yóo bukun ilé Israẹli,yóo bukun ìdílé Aaroni.

13. Yóo bukun àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,ati àwọn ọlọ́lá ati àwọn mẹ̀kúnnù.

Orin Dafidi 115