Orin Dafidi 113:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ yin OLUWA!Ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ OLUWA.Ẹ yin orúkọ OLUWA.

2. Kí á yin orúkọ OLUWA,láti ìsinsìnyìí lọ títí laelae.

3. Láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn,kí á máa yin orúkọ OLUWA.

4. OLUWA ju gbogbo orílẹ̀-èdè lọ,ògo rẹ̀ sì ga ju ọ̀run lọ.

5. Ta ló dàbí OLUWA Ọlọrun wa,tí ó gúnwà sí òkè ọ̀run,

Orin Dafidi 113